OMO OLORUN YIO BORI NINU IGBA TI O LE
Die ninu awon Juu to kuro nigbekun pada sile lati tun ile won ko, sugbon inu ota ko dun si won, won si nfe lati sa gbogbo ipa won lati da won duro. Sugbon awon Omo Israeli se okan giri lati se atako ota won, won si se aseyori gege bi ero won. Awon Juu bori awon ota won nipa atilehin ofin. Awon alase b’ola fun ebe won, oruko Olorun si di yinyin logo. A koo wipe nje nitori naa, bi o ba wa wu oba, je ki a wa inu ile isura oba ti o wa nibe ni Babiloni, bi o ba ri bee pe kinusi oba fi ase lele lati ko ile Olorun yii ni Jerusalemu, ki oba ki o so eyi ti o fe fun wa nipa oran yii. Nigba naa ni Dariusi oba pase, a si wa inu ile ti a ko iwe jo si, nibi ti a ta isura je si ni Babiloni. A si ri iwe kan ni Ekbatana ninu ilu olodi ti o wa ni gberiko Medea, ati ninu re ni iwe iranti kan wa ti a ko bayii. Ni odun kinni kirusi oba, kirusi oba naa pase nipase ile Olorun ni Jerusalem pe, ki a ko ile naa, ibi ti won o maa ru ebo. Ki a si fi ipile re lele sinsin, ki giga re je ogota igbonwo, ati ibu re, ogota igbonwo (Esra 5:17, Ezra 6:1-3). Niwon bi awon omo Israeli ti pinnu pelu oniruuru idojuko ti won ri, awon omo Israeli si se aseyori ni kiko tempili Olorun. Won see li oso, won si rubo itewogba si Olorun.
EKO
Awon ti o ba nsi Olorun ko ni kabamo fun sise bee, sugbon a o b’ola fun ojuse won. Awon omo Olorun lee ni ipenija ati akoko ti o ole, sugbon won yio bori nikehin. Won o la igbenija koja , won o si yin oruko Olorun. Niwon bi o ti je pe opolopo ere yi o wa fun awon eniyan Olorun, o ye ki gbogbo eniyan ni irepo pelu Olorun, ki won sin in, ki won ba lee je awon anfani re.
ADURA
Olorun olufe, se mi ni eni ti o ni ife re tokantokan, ki emi le yege ni gbogbo aye mi. Mo ni imoye pe iwo yi o se atilehin awon ti o ba b’ola fun o, o ki yio je kiota won fi won se yeye, ki a le yin oruko re logo nitori won. Jowo fun mi ni, okun lati sise pelu re, ki emi si je awon anfani re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
