OLUWA KI YIO TA O NU
Paulu jewo ni gbangba nipa asise re gege bi oluse inunibini si kristieni, o saleye wipe ‘Eese ti eyin fi roo si ohun ti a ko le gbagbo, bi Olorun ba ji oku dide, emi tile ro ninu ara mi nitooto pe, o ye ki emi ki o se opolopo ohun odi si oruko Jesu ti Nasareti. Eyi ni mo si se ni Jerusalemu awon pupo ninu awon eniyan mimo ni mo ha mo inu tuubu, nigba ti mo ti gba ase lodo awon olori alufaa, nigba ti won si npa won, mo ni ohun sii. Nigba pupo ni mo se won nisee ninu gbogbo Sinagogu, mo nduu lati mu won so oro-odi nigba ti mo soro si won gidigidi, mo se inunibini si won de ajeji ilu. (Awon Aposteli 26:8-11) Paulu tun salaye iyipada otun nigba ti o ba Jesu Kristi pade, o wipe ‘Ni osan gangan oba, mo ri imole kan lati orun wa, o ju riran orun lo, o mole yi mi ka ati awon ti o nba mi re ajo. Nigba ti gbogbo wa si subu lule, mo gbo ohun ti nfo si mi ni ede Heberu pe, Saulu, Saulu, eese ti iwo fi nse inunibini si mi? ohun irora ni fun olati tapa si egun. Emi si wipe iwo ta ni Oluwa? Oluwa siwi pe, emi ni Jesu ti iwo se inunibini si. Sugbon dide, ki o si fi ese re tele nitori eyi ni mo se farahan o, lati yan o ni iranse ati eleri fun awon wonni ti iwo ti ri, ati ohun won-on-ni ti emi o fi ara han fun o.
(Awon Aposteli 26: 13-16)
EKO
Jesu Kristi ngba enikeni ti o ba to o wa fun igbala, ko ko enikeni sile rii. Ohunkohun ibaaje ijakule wa ti atehinwa, Kristi yi o dariji elese ti o ba ronupiwada ese re, yi o foju fo iru ese kese ti won ti le da, yi o si fo won mo. Kristi fun awon eniyan mimo re ni aye titun ati oruko titun, ohun amuye lati le je anfani ijoba Olorun ni jijewo ese ati gbigba Jesu Kristi bi Oluwa. Enikeni ti o ba gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala re, oju ko ni tii sugbon yi o je ere iye ayeraye.
ADURA
Nigba kan ri mo sonu sinu ese sugbon bayi mo di eni igbala nipase Jesu Kristi,Kristi omo Olorun ti yi aye mi pada, o wa mi ri, o dari ese mi ji mi, o ra okan mi pada kuro ninu idalebi ina orun apadi. Igbe aye mi gba iyipada ninu Jesu Kristi, mo di eni igbala, eyin Olorun logo!! a ti ko oruko mi sinu iwe iye, igbala ijoba Olorun si to simi. Eyin Jesu Kristi logo fun gbigba emi elese la, mo bere ki Jesu Kristi fun mi ni ore ofe lati ye fun ijoba orun. Amin.
