OLORUN YIO GBEJA AWON IRANSE RE
Alase Juda fi iya je Jeremiah nitori pe o so otito okan Olorun. Won juu sinu koto, ni ireti pe ki ebi pa ku. Bibeli royin wipe ‘Won si mu Jeremiah, won si soo sinu iho Malkiah omo Hammeleki, ti o wa ni agbala ile-tubu, won fi okun so Jeremiah kale sisale. Omi ko si ninu iho na, bi ko se ere Jeremiah si ri sinu ere naa (Jeremiah 38:6)
EKO
A ngbe nile aye nibi ti eniyan nb’ola kekere fun Olorun, won a si maa bu iranse Olorun, lati pa Olorun lara. Opolopo igba ni won a maa bu iranse Olorun, aigboye, igbekale odi. Jehofa ko lee layo nibi ti awon eniyan ti nbu awon iranse re. Niwon bi won se je asoju Olorun, yi o gbesan. Awon ti o nbu, won yio gba esan pada. Eyi ti a o fi siwahu si awon iranse Olorun, o ye ki a mo bi ise won se ri ki a si bola fun won. Iranse Olorun je Woli Olorun, won nso ero okan Olorun, iranse Olorun yio ma so otito inu bibeli ni gbogbo igba, awon eniyan yio si maa tele bi won se ndari. Olorun ni won a ji hin fun, ki a mase mu won pelu owo yepere, ki a mase hale mo won nipa ojuse won, o ye ki a tele ase won. O se Pataki ki a bola fun iranse Olorun, nitori pe won je asoju Olorun. Ohunkohun ti a ba se si won, Olorun ni a se won si. Enikeni ti o baa nreti iranlowo lati odo Olorun, ki o mase aibola fun iranse re.
ADURA
Olorun Olufe, mo mo pe ohun ti o buru ni ki a mase b’ola fun iranse re. Iwo yio fiya je awon ti o yan ise Pataki nitorinaa mo setan lati maa b’owo fun awon iranse re. Emi yio ti won lehin gege bi ipa mi, ki won ba lee tesiwaju ninu ise ti o pe won si. Fun mi ni ore-ofe lati maa se ohun to to. Mo nlo akoko yi lati maa gbadura fun gbogbo iranse re ni gbogbo agbaye, ki o fi ifami ororo yan won ki won tesiwaju lati maa sin o. Fun won ni agbara lati maa gboran si ase re, ki o si bukun won ni gbogbo ona won. Ki a le yin oruko re ninu aye won. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
