OLORUN YIO DA IKOLO RE PADA
Olorun mu ileri re lori Israeli omo re se, wipe oun yi o saanu won, oun o si da gbogbo ikolo won pada. Olorun so wipe, ‘Bayi ni Oluwa wi, bi emi ko ba pase majemu mi ti osan ati ti oru, pelu ilana orun ati aye. Nigba naa ni emi iba ta iru omo Jakobu nu ati Dafidi, iranse mi, ti emi ki o fi mu ninu iru omo re lati se alakooso lori iru omo Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, nitori emi o mu ki igbekun won ki o pada bo, emi o si saanu fun won. (Jeremiah 33:25-26)
EKO
Olorun je alaanu ati olore-ofe, ko ni ta awon omo re nu titi aye. Olorun ti o da orun ati aye, yio ranti majemu ti o da pelu Abrahamu, Isaaki ati Jakobu. Yio ranti awon omo won, yio si bukun won. Kristeni se alabapin eto pelu awon iran Abrahamu (Ati pe wa sinu majemu kan naa nipase Jesu Kristi) Nitori naa, ki won ki ara won ku ori ire. Awon ti ko tii gbe ese igbagbo, nipa jijewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won, ki won se bee nisinyi.
ADURA
Inu mi dun wipe, mo ti jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala mi, Majemu Abrahamu ni lati wa si imuse ninu aye mi, Mo gbadura ki Olorun fi ese mi mule ni agbala ibukun re ki emi le je anfani re titi lae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
