OLORUN KO NI PIN OGO RE PELU ENIKENI
Olorun a maa lo Oloro ati eniyan lasan fun ise akase re ni yiyato si ogbon omo eniyan awon alai lagbara eniyan fun ise ogo re, a si maa se ara re logo ninu won. Bibeli tile wipe, ‘sugbon Olorun ti yan awon ohun were aye yi lati fi daamu awon ologbon, Olorun si ti yan awon ohun ailera aye lati fi daamu awon ohun ti o ni agbara. (1 Korinti 1:27)
EKO
Olorun nfe lati gba ogo ti o ye fun ise re, O korira lati pin ogo re pelu okunrin ati obinrin elera ara. Eledaa maa nsogo nigba ti o ba ni eniyan lasan ti o nmu lo; agbara Olorun. Iru eyi mu ki okan awon eniyan si lara iranse si Olorun funra re. Fun apeere Jesu Kristi yan awon pejapeja gege bi awon omo ehin re (yato si awon die) lati yi gbogbo aye pada si ijoba Olorun. Awon oniwaasu ti ko kawe, wa nkoni lati inu iwe-mimo (Bibeli mimo) won sin se ise iyanu, awon eniyan si gba ipenija lati josin pelu Olorun iyanu.
ADURA
Olorun olufe, jowo lo mi fun Ogo Re. Fun mi ni okan irele, ki emi si wulo fun ijoba re. Bi o ba si ti lo mi, mase je ki emi gba Ogo re fun ara mii sugbon je ki emi le maa dari awon eniyan si O. Ka mi ye fun ijoba re, ki emi si gba ade Ogo re nikehin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
