MAA FI IGBAGBO SI OJUSE
Awon baba asaju ninu igbagbo, gbe igbese ti ko wopo ninu igbagbo, eyi ti o tako aniyan ibugbe won, oju ko si ti won. Olorun tiwon lehin, o si b’ola fun won, won si di akinkanju ti ko wopo. Fun apere ‘Nipa igbagbo ni Mose, nigba ti o dagba, o ko ki a maa pe oun ni omo omobinrin Farao. O kuku yan ati maa ba awon eniyan Olorun jiya ju ati je faaji ese fun igba die. O ka egan Kristi si oro ti o po ju awon isura Egipti lo nitori ti o nwo ere naa. Nipa igbagbo ni o ko Egipti sile ni aiberu ibinu Oba, nitori ti o duro sinsin bi eniti o nri eni airi. Nipa igbagbo ni o da irekoja sile, ati ibuwon eje, ki eni tin pa awon akobi omo ki o ma baa fi owo kan won. Nipa igbagbo ni won la okun pupa koja bi eni pe iyangbe ile, ti awon ara Egipti dan wo, ti won si ri. (Heberu 11:24-29)
EKO
Onigbagbo ni lati mu igbagbo lo ninu ipokipo ti won ba wa. Ose Pataki ki a mu igbagbo si oju ise. Igbagbo ni o mu ki Kristeniti ni itumo, laisi igbagbo, a ko yato si keferi. Olorun je Olorun igbagbo, onigbagbo ni lati je eni ti o gbagbo bakanaa. A ni lati gbe pelu igbagbo, rin pelu igbagbo, huwa pelu igbagbo. Amulo igbagbo wa, yi o je ki ohun gbogbo yipada si rere fun wa. Nipa imulo igbagbo wa, a o bi awon oke lule, a won koto ni a o di pa. Igbagbo yio mu ki a bori ninu ohun gbogbo, a o ni idi - eri lati yin Olorun logo. Eni kookan omo Olorun nilati ni oro imuduro, ki gbogbo Kristeni lee wipe Olorun, ohun gbogbo lo see se.
ADURA
Ni oruko Jesu Kristi, mo jewo igbagbo igbala mi. Ni oruko Jesu Kristi, mo kede iduro sinsin jije Kristeni mi. Emi yio duro, nko ni subu ninu ore-ofe Oluwa. Ni oruko Jesu Kristi mo kede isegun mi lori gbogbo ohun ti aye mi. Nipa ase ti Jesu Kristi mo bori ijoye, ati awon olola. Mo kede ara mi ni asegun lori ohun gbogbo. Mo je asegun ati eleri. Lati oni lo, ilekun iserere, itesiwaju ati igbega ni yio bere si si fun mi ni gbogbo ona. Emi yio se aseyori ninu ohun gbogbo ti mo ba dawole. Emi o si se rere ninu ile, emi yio se rere ni oko, emi o se rere ni ohun gbogbo ti mo baa nse, orin eri mi yio wa titi aye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo se ijewo igbagbo mi. Amin
