IYIN TO SE ITEWOGBA
Oba Dafidi ongbe igbe aye kikorin ati jijo niwaju Olorun. O feran lati maa fi orin sipe/gbadura. Ni opo igba, Olorun maa nyi orin Dafidi pada si asotele. Olorun fi aini inu didun si iwa ailani si ofin oro re. Emi Olorun so wipe Eyin Omo eniyan, e o si ti so ogo mi di itiju pe to, eyin o ti fe asan pe to, ti e o si maa wa eke kiri. Sugbon ki e mo pe Oluwa ya eni ayanfe soto fun aa re. Oluwa yoo gbo nigba ti mo ba ke pee. Eduro ninu eru, e ma si se se, e ba okan yi soro lori eni yin, ki e si duro jee (Orin Dafidi 4:2-5)
E ru ebo ododo, ki e si gbeke yin le Oluwa.
EKO
Olorun feran iyin, sugbon o fe ki a je olotito sii. A ko ni lati fi orin iyin wa se riba fun Olorun, nigba ti a ngbe igbe aye ese idibon wa ko ni mi Olorun, o fe ironupiwada to peye. Bi a ko ba fe ki iyin wa jasi fifi akoko sofo, a nfe ki Olorun gbe ebo orin wa, a nilati je olotito. Olorun orun yi o yayo lori wa ti a ba je olooto sii, yi o bukun wa, ti a ba ni idapo to joju pelu re.
ADURA
Olorun Olufe mo fe fun o ni iyin to kun, ti yi o si se itewogba ni gbogbo akoko. Nitori naa, ka mi ye fun ojuse pataki yi. Je kinni idapo otito pelu re. Mo mo wipe, mo le je olotito omo re ni pa iranlowo Emi Mimo, nitorina bukun mi pelu Emi Mimo re. Je ki emi maa gbe ni Alafia, ki emi si maa je awon anfani re ni gbogbo ojo aye mi gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
