GBAGBO NINU AWON ILERI OLORUN
Bibeli kilo fun wa ki a mase gbeke le eran ara, nitori won yio jawa kule. A rowa lati gba Olorun gbo, ti ko ni ja wa kule. A ti koo, ‘bayi ni Oluwa wi, egbe ni fun eni ti o gbekele eniyan, ti o fi eleran ara se apa re, eni ti okan re si si kuro lodo Oluwa. Nitori pe yio da bi alaini ni aginju, ti ko si ri pe rere nbo, sugbon yio gbe ibi iyangbe ile won-on-ni ni aginju, ile iyo ti a ki igbe. Ibukun ni fun eni to gbekele Oluwa, ti o si fi Oluwa se igbekele re. Yio si di bi igi ti a gbin lebaa omi, ti o ni gbongbo re lebaa odo, ti ki yio beru bi ooru ba de, sugbon ewe re yio tutu, ki yio si ni ijaya ni odun oda, bee ni ki yio dekun lati maa so eso. (Jeremiah 17:5-8).
EKO
Eniyan ko pe, sugbon Olorun pe, nitori naa a ro Omo Olorun lati fi igbekele won sinu Olorun. Olorun ko ni alebu ara, sugbon eniyan ni. Eniyan le yi okan tabi ipinu re pada nigba kugba, ole jani kule. Eni ti a gbekele le ku. Olorun a maa duro lori ileri, o si wa titi ayeraye. O ni gbogbo ase lori ohun gbogbo. Otito ni oro re, ko si enikeni ti olee pe nija. Bibeli kun fun opolopo ileri re fun awon Omo re. A le gbo ohun ileri re ninu iwe Jeremiah 29:11 (Nitori emi mo ero ti mo ro si yin ni Oluwa wi, ani ero alaafia, kii se fun ibi, lati fun yin ni igba ikeyin ati ireti) nitori naa, onigbagbo ni lati ni igbagbo ninu Olorun. Ki a ni igboya si awon ileri re, ki a si maa ka won sinu aye wa, a ni lafia, oro ati beebee lo
ADURA
Olorun olufe, iwo nikan lo wa, ti kii jani kule. Gbogbo eniyan lo le jani kule, nitori eyi gbogbo igbekele mi yio wa lodo re. Mo jewo ijolotito mi lati sin o, igbekele mi a si wa lodo re fun awon aini mi gbogbo. Ki igbagbo mi wa ni ibamu pelu ijeri nigba gbogbo, ki o rorun fun mi lati wipe mo mo Olorun ti mo nsin, yio yo mi ninu ewu gbogbo, yio si ba aini mi pade. Jowo ba gbogo aini mi pade, je ki emi ni eri didara re, ti mo le pin pelu awon ti o ku. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
