FI IMORE HAN SI OLORUN
Olorun nfe ki a fi okan imore han fun awon aseyori wa, ki a mase se isogo ninu ara. Eledaa ko fe ki a sogo ninu aseyori eniyan tabi oro, bi enipe a ko o jo pelu igbiyanju wa. Aseyori wa gbogbo wa lati owo Olorun, a nila ti re ara wa sile ki a si yin oruko re. Bibeli ko wa bi a se le yayo aseyori wa, bi a ti koo ‘Bayi ni Oluwa wi, ki ologbon ko ma sogo ninu ogbon re, bee ni ki alagbara ko ma sogo nitori agbara re, ki oloro, ko ma sogo nitori oro re. Sugbon ki enikeni ti yio ba maa sogo, ki o se e ninu eyi pe, oun ni oye oun si mo mi pe Emi ni Olorun tin se aanu ati idajo ati ododo ni aye, nitori inu mi dun ninu ohun wonyi, ni Oluwa wi. (Jeremiah 9:23-24)
EKO
Onigbagbo ni lati mo bi a se nyin Olorun logo nipa aseyori won. Omo Olorun ye ki o le so wipe nipa oore-ofe Olorun, mo ri bi mo ti ri. Awa Kristeni ni lati ni oye pe, Olorun ni nbe lehin aseyori wa gbogbo. Oti mu wa dehin yi nipa agbara igbala re, kii se nipa igbiyanju ara wa. Nitori naa a nilati maa fi imore han fun un nigba gbogbo. A le maa toka si aseyori wa, ki a si sogo, sugbon o ye ni gbogbo igba lati maa bola fun Olorun.
ADURA
Olorun olufe, mo dupe fun gbogbo aseyori mi, iwo ni igi lehin ogba/aseyori mi, lai si re, emi ko lee de ibi ti mo wa looni. O ti fun mi ni ohungbogbo ti mo ni, lai si re nba ma ni ohunkohun ti mo ni. Nitori naa, emi yio maa yino ni gbogbo ojo aye mi. Jowo fun mi ni ore ofe lati mo riri didara re, mase je ki njo ara mi loju, lati maa dari ogo re si aseyori igbiyanju ara mi. Je ki eri mi ki o maa jasi iyinlogo oruko re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
