ESE JE ILEKUN SISI FUN OTA
Olorun gba fun awon Babeli lati segun Israeli ati Juda nitori ese won, sugbon Olorun se ileri imupada bo sipo fun awon orile meji yi, nitori pe won ronupiwada. Olorun so wipe oun yio mu Israeli ati Juda pada sipo, yio fiya je Babeli ti o fiya je won. Olorun soro lati enu Jeremiah wipe ‘Ni ojo won-on-ni ati ni akoko naa, ni Oluwa wi awon omo Israeli yio jumo wa, awon ati omo Juda, won o maa lo tekuntekun, won o lo, won o saferi Oluwa Olorun won. Won o maa beere ona sioni, oju won yio si yi sibe won o wa, won o dara po mo Oluwa ni majemu ayeraye, ti a ki yio gbagbe. Awon eniyan mi ti je agbo-ogun tan ti o sonu, awon Oluso-agutan won ti je ki won sina, won si ti je ki won rin kiri lori oke, won ti lo lati ori oke nla de oke kekere, won ti gbagbe ibusun won. Gbogbo awon ti o ri won, tipa won je, awon ota won si wipe, awa ko jebi, nitori pe, won ti se si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awon baba won, ani Oluwa. E sa lo kuro ni aarin Babeli, e si jade kuro ni ile awon ara kaldea, ki e si je bi abuko niwaju agbo-eran. Nitori woo, emi gbe dide, emi o si mu apejo awon orile-ede nla, lati ile ariwa wa sori Babeli, won o si tegun sii, lati ibe wa ni a o si ti mu un, ofa won yio da bi ti akoni, amoye, okan ki yio pada ni asan. (Jeemiah 50:4-9)
EKO
Olorun je Olorun ife ati aanu, yio dariji elese ti o ba ronupiwada kuro ninu ese won. Ese nsi ilekun fun ota lati fi iya je awon omo Olorun. Sugbon logan ti won ba ronupiwada, iru ilekun bee a ti pada. Olorun yio gba awon omo re pada ti o ba too wa. Yio we elese mo pelu eje omo re Jesu Kristi. Olorun yio fun elese ti o ba ronupiwada ni ebun iye ainipekun ni orun. Elese ti ko ba ronupiwada, o ti padanu idariji ati gbigba pada (imupada) ko le ri Olorun ni opin aye re. (Enikeni ti o ba ko igbala ti Jesu Kristi, ni a npe ni elese, ko le wo ijoba orun rere).
Iye awon ti o jewo ese won, ti won si gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won ni yio ba Olorun joba ni orun rere. Nitori naa a nbe gbogbo eniyan lati ronupiwada ese won, ki won si jewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won, ki won le di eni igbala.
ADURA
Olorun Olufe mojewo pe moje elese, mo ti se niwaju re, emi ko si ye ni eni ti a ba pe ni omo re, sugbon loni, mo jewo ese mi, mo si ronupiwada ninu re. Lati akoko yi, mo fi gbogbo aye mi fun o, emi yio sin o ni gbogbo aye mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, si ka mi ye lati joba pelu re ni orun-rere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
