ATI FI ASE FUN WA LATI BORI NIPASE AGBARA JESU
Gbogbo ise iyanu ti Jesu Kristi se ni a ko sinu iwe mimo won si je eyi ti o yato, o ji oku dide, o wo awon alaisan san, o si bo opolopo egberun awon ti ebi npa pelu isu akara die ati eja wewe die. Jesu tile tun se awon ise iyanu miran ti o ru awon omo ehin re soke. Jesu ba afefe ati iji soro, won si gbohun re. Bibeli rohin isele kan ti a kope o si ni ojo kan, o si wo oko kan lo ti oun ti awon omo-ehin re, o si wi fun won pe, e je ki awa ki o rekoja lo si iha keji adagun. Won si siko lo. Bi won si ti nlo, o sun, iji nla si de, o n fe ni oju adagun; won si kun fun omi, won si wa ninu ewu. Won si too wa, won si jii wipe olukoni, olukoni, awa gbe, nigba naa ni o dide, o si ba efufu oun riru omi wi, won si da, idake-roro si de. O si wi fun won pe, igbagbo yin da? Bi eru ti nba gbogbo won, ti ha sin nse won, won nbi ara won pe, iru Okunrin ki ni eyi nitori o ba efuufu ati riru omi wi, won si gbo tire.
(Luke 8:22-25).
EKO
Jesu Kristi ni agbara ti ko se dojuko ti o le fi le eniyan ati awon emi jade. O ni agbara nla ti enikeni ko le dojuko. Eniyan teriba fun ase jesu Kristi, emi esu si teriba pelu. Iwe mimo si wipe iwo gbagbo pe olorun kan ni n be; o dara; awon emi esu pelu gbogbo, won si wariri. (Jakobu 2:19).
Ase ti nbe ni oruko jesu Kristi nle satani lere nigbati a ba lo oruko yi. Kii se pe jesu Kristi ni agbara nla nikan, O fun awon omo ehin re ni iru ase re. Awon ti o gbagbo ninu jesu Kristi le lo ase oruko re lati bori tabi gbe igbe aye asegun. Kini idi? Nipa igoke re si orun re, o se alabapin agbara re pelu awon ti o gbagbo” Looto ni mo wi fun yin, ohunkohun ti eyin ba de ni aye, a o dee ni orun, ohunkohun ti eyin ba si tu ni aye, a o tuu ni orun (Matiu 18:18). Niwon igba ti jesu Kristi ti seto isegun fun awon ti o ntele lati le gbe igbe aye asegun, Onigbagbo/Kristieni ni lati gbiyanju lati lo anfani yi. Onigbagbo ko ni lati beru, gbe ni itiju tabi kabamo, a ni lati gbe ori wa soke lati je anfani ase ti nbe ninu Kristi ki a wo inu isegun ni gbogbo ona wa.
ADURA
Jesu Kristi, mo gbagbo pe mo ba o pin ninu agbara ise iyanu re, mo si duro lati mu lo ase ti nbe ni oruko re fun ikede isegun mi, Nitorina pelu igboya, mo so awon oro wonyi; mo pase ki satani kuro ni gbogbo ona mi. Mo pase ki gbogbo ide satani ja ni oruko Jesu. Mo kede ominira mi ni oruko jesu, lati akoko yi lo, ohun gbogbo ni lati ma sise papo fun anfani mi. Akoko mi ti de lati kegbe isegun, ati korin hosanna iyin si oruko olorun mi. O seun jesu Kristi nipa fifun mi ni isegun nla nipase ase oruko re. Amin.
