A PA AWON ONIGBAGBO L'ASE LATI DURO SINSIN
Bibeli fun awa Onigbagbo ni ireti pe gbogbo ruke rudo aye yio dopin laipe fun awon eni mimo Olorun, a o si wa pelu Olorun titi ayeraye. A ti koo pe ‘Oun o si se idajo laarin opolopo eniyan yoo si ba alagbara orile-ede rere wi, won o si fi ida won ro obe irin-itule ati oko won ro doje, orile ede ki yoo gbe ida soke si orile-ede bee ni won ki yoo ko ogun jija mo. Sugbon won o jokoo olukuluku labe ajara re, ati labe igi opoto re enikan ki yoo si seru ba won, nitori enu Oluwa awon omo-ogun ni o ti soo.
(Mika 4:3-4)
EKO
Ijiya yi o wu ki omo Olorun maa je ki yi o je fun titi aye, yi o wa si opin ni ojo kan. Gbogbo awon omo Olorun ni yio kuro ninu aye buburu yi lati lo sodo Olorun ni orun titi ayeraye, ni orun Jesu Kristi ni yi o je aare wa, a ki yio jiya mo. Alafia pipe yi o wa laisi ibanuje kan, awon eniyan yi o mu omi Alafia ti o unsan lati ookan aya Olorun wa, nigba ti ere isegun unduro de Onigbagbo, gbogbo Kristieni ni lati mu iduro won sinsin pelu Olorun. Ki a fara da idanwo ati inilara eyi keyi ti ota le fi doju ko wa, niwon igba ti a mo wipe ere Olorun ti ko ni opin unduro de wa ni orun.
ADURA
Olorun olufe, mo feran re ju wura ati fadaka lo, mo feran re ju inunibini ati ininilara. Ilepa mi ni lati de orun lehin irin ajo mi nile aye yi, nitorina mo yonda aye mi fun o looni, mo gba Jesu Kristi ni Olugbala tooto mo si gbaa ni Oluwa mi, jowo mu mi sun moo sii, ki nsi fi tokan tokan sin o ni gbogbo ojo aye mi gbogbo, ki emi le ye lati je igbadun ayeraye pelu re ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
