MA SE FI OJU DI OLORUN; O LAGBARA LORI OHUN GBOGBO
Oba Siria ati awon Omo ogun re foju di Olorun, won yepere abo Olorun. Nigba ti awon Olorun kekeke (orisa) ti ja awon Siria kule nipa gbigbogun ti awon omo Israeli. Awon Siria wa so wipe, Olorun ti o fun Israeli ni isegun ni agbara lori oke, ni ibi ti won ti jagun. Nitori naa, won gbogun ti Israeli ni petele. Sibe won padanu, Israeli segun won. Bibeli wipe awon iranse oba Siria si wi fun un pe, Olorun won, Olorun oke ni, nitori naa ni won se ni agbara ju wa lo, sugbon je ki a ba won ja ni petele, awa o si ni agbara ju won lo nitoto. Nitori naa, emi o fi gbogbo opolopo eniyan yii le o lowo, eyin o si mo pe, Emi ni Oluwa. (1 Awon Oba 20:23, 1 Awon Oba 20:28).
EKO
Olorun ko lopin ninu agbara, enikeni to ba kere agbara Olorun yi o kabamo. Olorun ni gbogbo agbara, o si lee se ohun gbogbo. A ko lee foju rii, kii ree. Agbara Olorun ju gbogbo agbara ti o ti wa lo. Olorun ni Jehofa, oun si ni eledaa. O ronu, o si da ohun gbogbo bo se wuu. Olorun nse akoso agbaye, o si ni agbara to bee ti ko ye ki enikeni mase bowo fun-un. Gbogbo eda nilati maa sin Olorun ki gbogbo eniyan si bola fun ni gbogbo igba.
ADURA
Olorun Olufe, mo bola fun o, nitori pe iwo ni Oba awon Oba, ati Oluwa awon Oluwa. Agbara re ga, ijoba re si daju. Mo feran re, mo si gbara le o. Ohunkohun ko ni mu mi sin orisa, ohunkohun ko ni mu kin sakawe re pelu ohun kan kan. Iwo ni Oluwa mi, okun mi, ati igboya mi. Iwo ni eri mi, iwo si ni eredi wiwa laye mi. Ijolooto mi yio wa fun o, ati idaniloju igbala mi nipase omo re Jesu Kristi ko ni ye laelae. Mo jeeri igboya ati ijolooto mi si o, ninu Omo re Jesu Kristi, Amin.
