GBA OLORUN GBO FUN IGBALA RE
Sakeu ti o je oloro ni irele lati gba igbala Jesu Kristi, o gun igi lo ni iyara lati ri Jesu, Mesaya si ri igbinyanju re o si gbaa la. Bibeli wipe ‘Si kiyesii okunrin kan wa ti a npe ni Sakeu, o si je olori agbowoode kan, o si je oloro. O si nfe lati ri eni ti Jesu nse ko si le rii nitori opo eniyan, ati nitori ti oun se eniyan kukuru. O si sure siwaju, o gun igi Sikamore kan, ki o ba le rii nitori ti yoo koja lo niha ibe, nigba ti Jesu si de ibe, o gbe oju soke o sii rii, o si wi fun un pe Sakeu, yara ki o si sokale, nitori emi kole saiwo ile re lonii.
(Luku19:2-5)
EKO
Jesu Kristi yi o gba onirele la sugbon ko ni gba onigberaga la, onirele yi o gbojege ese won, won o yi pada sugbon agberaga yi o duro ninu ese won, bi Kristi ba tile fe gba won la. Kristi yi o silekun igbala re sile fun gbogbo elese titi di akoko ti yoo ti pa. enikeni ti o ba warunki sinu ese yi o dara re lebi, iru eni bee ko ni ni anfani lati lo si orun rere. Sugbon yi o lo sorun ina apadii, nitori naa gbogbo eniyan ni lati ronupiwada ki o to peju. Enikeni ti o ba niwa irele ni lati gba adura fun igbala.
ADURA
Jesu Kristi olufe mo jewo re gegebi omo Olorun alaaye ti o ku fun ese mi. o ku lori igi agbelebu, o ji dide kuro ni ipo oku lati le fun mi ni igbala. Mo gba o gbo, mo si gba o gegebi Oluwa ati olugbala mi, lati oni lo, mo kede ara mi pe mo di atunbi Kristieni. Emi yi o tele o, un o si sin o titi iyoku aye mi. Amin.
