MASE FI IGBAGBO RE NINU KRISTI TAFALA
A nro gbogbo Kristeni ki won ripe idapo won pelu Olorun se deede ko si Kristeni ti o ye ki o mu iduro re ni yepere, sugbon olukuluku ni lati maa lepa, bi yio ti se le te Olorun lorun. Bi a ti koo ninu Bibeli ‘Nitorinaa, ki a fi ipilese eko Kristi sile, ki a lo si pipe, ni aitun fi ipile ironupiwada kuro ninu oku ise lele, ati igbagbo sipa ti Olorun. Ati ti eko ti iwenu, ati ti igbowole-ni ati ti ajinde oku, ati ti idajo ainipekun. Eyi ni awa o si se, bi Olorun fe. Nitori awon ti a ti la loju leekan, ti won si ti to ebun orun wo, ti won si ti di alabaapin Emi Mimo. Ti won si ti subu kuro, ko le see se lati so won di otun si ironupiwada nitori won tun kan omo Olorun mo agbelebuu si ara won ni otun, won si doju tii ni gbangba (Heberu 6:1-6)
EKO
Isin awon Kristeni je esin ti o ni iwa oto. Esin yi fihan wa, awon iwa amuye ki a to le wonu ijoba orun rere. A be gbogbo Kristeni ki won huwa bi Kristeni tooto. Ki a mase gbonjege igbala wa ti o se iyebiye. Gbogbo Kristeni ni lati mu inu Olorun dun si ohunkohun ti a ban se. Eru pupo nbe fun Kristeni onirele okan, ti o nte Olorun lorun ni isesi won. Orun yio se aponle Kristeni ti o ba je olooto ninu aye yi, ati ni orun.
ADURA
Olorun Olufe, jowo fun mi ni ore-ofe lati sin o tokantokan. Fun mi ni okan irele ati agbara lati sise fun o, fun mi ni okun nipase Emi Mimo ki emi le ba ireti re lori mi pade, ki emi le se aseyori ni aye yi ati ni orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere, Amin.